HYMN 802

Tune: 7s1. E fi ogo fun Baba

   Nipa Eni ti a wa

   O ngbo adura ewe 

   O nf’eti si orin won.


2. E fi ogo fun Omo 

   Kristi, ‘Wo ni Oba wa 

   E wa, e korin s’oke

   S’Od’agutan elese.


3. Ogo fun Emi Mimo

   Bi ojo Pentikosti

   Ru aya awon ewe 

   F’orin mimo s’eti won.


4. Ogo ni l’oke orun 

   Fun Eni Metalokan 

   Nitori ihin rere

   Ati ife, Olorun. Amin


English »

Update Hymn