HYMN 804

(FE 839)
Olorun reti pase agbara re" - Ps. 68:28
Tune: Baba Mimo Jo gbo gbe Omo Re1. DIDE tan imole, Imole Owuro 

   Jeki ogo Oluwa yo lara re

   Okunkun ese ti bo aiye mole 

   Sugbon ewa ayanfe ti jade.

Egeb: Wa ore mi, e wa k’a jo yo

      E ke Hosannah s’Oba Ogo 

      Apata aiyeraiye jowo

     mu ‘Ieri' re se.


2. Awon keferi y'o wa si‘imole Re 

   Awon Oba y’o teriba fun O

  Gbe oju re soke ki o wo yika 

  Siro ‘rawo, siro ‘bukun loke.

Egeb: Wa ore mi, e wa k’a jo yo

      E ke Hosannah s’Oba Ogo 

      Apata aiyeraiye jowo

     mu ‘Ieri' re se.


3. Omo alejo ni y'o mo odi re 

   Awon Oba y’o se ‘ranse fun o 

   Awon aninilara re y’o d'ofo 

  Y’o pa won elegan lenu mo.

Egeb: Wa ore mi, e wa k’a jo yo

      E ke Hosannah s’Oba Ogo 

      Apata aiyeraiye jowo

     se isadi wa.


4. Orun banuje ki y'o ran si wa mo 

   Osupa ekun wa mbo wa dopin 

   Emi Jehovah y'o mu oro mi se, 

   Lati mu Oba wa gunwa loke. 

Egeb: Wa ore mi, e wa k’a jo yo

      E ke Hosannah s’Oba Ogo 

      Apata aiyeraiye jowo se abo

     wa loke Re.


5. Mo se o ni wura asayan loni 

   Emi agbara mi mbe lara re 

   Abo aso eri kuro lara re 

   Aso eye la fi dipo fun O.

Egeb: Wa ore mi, e wa k’a jo yo

      E ke Hosannah s’Oba Ogo 

      Apata aiyeraiye nikan

     l'ope ye fun loni. Amin

English »

Update Hymn