HYMN 806

APA KINI (FE 841)
“Tali o dabi Re Olorun Elenu ni iyin”
- Eks. 15:111. OLORUN agbaiye,

   Owo ni f’Oruko re 

   Iwo l’agbekele, 

   lai ma je k’oju ti wa. 

Egbe: Bi kose pe O ko ile na, 

     Osise nse lasan, 

     Wo Alfa ati Omega 

     Ran iranwo re si wa.


2. Oba aiku, Airi, Mimo logo julo 

   Eni aiyeraiye, t’o gunwa 

   n‘nu ‘mole nla.

Egbe: Bi kose pe O...


3. L’aiye ati l’orun, tani a ba fi we O! 

   Eleda, Alase, Baba

   Olodumare.

Egbe: Bi kose pe O...


4. Iwo l’o da aiye, ati ohun inu re 

   O da awon orun, ati gbogbo

   ogun won.

Egbe: Bi kose pe O...


5. Baba wa olore, at’oniyonu julo 

   Eleru ni iyin, Olorun alagbara.

Egbe: Bi kose pe O...


6. Metalokan lailai, Baba, 

   Omo on Emi 

   Ipilese, Opin, Mimo Awamaridi.

Egbe: Bi kose pe O...


7. Ogo f’oruko re, t’o ju 

   gbogbo iyin lo

   Iwo ni yin ye fun, tit’ aye 

   ainipekun.

Egbe: Bi kose pe O ko ile na, 

     Osise nse lasan, 

     Wo Alfa ati Omega 

     Ran iranwo re si wa. Amin

English »

Update Hymn