HYMN 809

(FE 844)
"O san lati gbekele Oluwa”
 - Ps. 118:81. ARE mu o, okan re poruru 

   So fun Jesu, so fun Jesu

   Ibanuje dipo ayo fun o? 

   So fun Jesu nikan.

Egbe: So fun Jesu, so fun Jesu 

     On l’ore t’o daju

     Ko tun s’ore

     Ati ‘yekan bi Re 

     So fun Jesu nikan.


2. Asun-dekun omije l’o nsun bi? 

   So fun Jesu, so fun Jesu

   O l‘ese to farasin f’enia?

   So fun Jesu nikan.

Egbe: So fun Jesu...


3. ‘Banuje teri okan re ba bi? 

   So fun Jesu, so fun Jesu

   O ha ns’aniyan ojo ola bi? 

   So fun Jesu nikan.

Egbe: So fun Jesu...


4. Ironu iku mu o damu bi? 

   So fun Jesu, so fun Jesu 

   Okan re nfe ijoba Jesu bi? 

   So fun Jesu nikan.

Egbe: So fun Jesu, so fun Jesu 

     On l’ore t’o daju

     Ko tun s’ore

     Ati ‘yekan bi Re 

     So fun Jesu nikan. Amin

English »

Update Hymn