HYMN 81

SS. 207 8s (FE 98)
“Eyo ni Oluwa” - Ps. 68:31. E YO nin‘Oluwa, e yo

   enyin olokan diduro

   At‘enyin t’ase l’ayanfe

  Mu ‘banuje kuro l’okan nyin.

Egbe: E yo, e yo, e yo nin’ Oluwa, 

      e yo. 2ce


2. E yo n’tori On l’Oluwa,

   L’ aiye ati l’orun pelu

   O njoba nipa ase Re,

   O l'agbara lati gbala.

Egbe: E yo, e yo...


3. Nigbati ogun ba gbona

   T‘ota ba fere segun nyin

   Ogun Jesu ti a ko ri,

   Po ju gbogbo otan nyin lo.

Egbe: E yo, e yo...


4. B’osan d‘orun mo nyin loju,

   T’okunkun re nderu ba nyin

   E ma je k’okan nyin baje

   Gbekele tit’ ewu yio tan.

Egbe: E yo, e yo...


5. E yo nin’Oluwa, e yo

   E f’orin didun yin logo

   Fi duru, fere, at’ohun

   Korin Halleluyah kikan.

Egbe: E yo, e yo... Amin

English »

Update Hymn