HYMN 810

S.M. (FE 845) 
“Gbogbo aiye ni yio ma sin O"
 - Ps.66:41. WA, rohin Re yika 

   K’a si korin ogo 

   Alagbara li Oluwa 

   Oba gbogbo aiye.


2. On l'O da won ibu

   O pala fun okun

   Tire ni gbogb’ awon odo 

   At'iyangbe ile.


3. Wa, wole n’ite Re 

   Wa, juba Oluwa

   lse owo Re l‘awa se, 

   Oro Re l'o da wa.


4. Gbo ohun Re loni

   Ma si se mu binu

   Wa, bi eni ayanfe Re

   Jewo Olorun re. Amin

English »

Update Hymn