HYMN 811

H.C 421 8s 7s (FE 846)
"Awon ologbon yio si ma tan bi
imole ofurufu" - Dan. 12:31. TAL’awon wonyi bi ‘irawo 

   Niwaju ite Mimo
 
   Ti nwon si de ade wura 

   Egbe ogo wo l’eyi 

   Gbo! nwon nko Halleluya

   Orin iyin Oba won! 


2. Tali awon ti nko mana

   T’a wo l’aso ododo?

   Awon ti aso funfun won

   Y’o ma funfun titi lai

   Beni ki y’o gbo lailai

   Nibo l’egbe yi ti wa? 


3. Awon wonyi l’o ti jagun 

  F’ola Olugbala won 

  Nwon jijakadi titi iku 

  Nwon ki b'elese k'egbe

  Wonyin ni ko sa f’ogun 

  Nwon segun nipa Kristi.


4. Wonyi l'okan won ti gbogbe

   Ninu ‘danwo kikoro

   Wonyi ni o ti f’adura

  Mu Olorun gbo ti won 

  Nisisyi won segun

  Olorun re won lekun.


5. Awon wonyi l’o ti sora

  Ti won fi fe won fun Krist’

  Nwon si y’ara won si mimo 

  Lati sin nigbagbogbo

  Nisisiyi li orun

  Nwon wa l’ayo l’odo Re. Amin

English »

Update Hymn