HYMN 812

8.8.6. D
Tune: “Lehin aye buburu yi”1. EMI ogbon, to oju wa 

   Kuro ninu asan aye 

   S’oto on ‘fe orun 

   Emi oye ti o daju

   Fi mole orun fun wa 

   Lati wa nkan toke.


2. Emi ‘moran s’Amona wa 

   F’ijakadi aye ko wa

   K’a gba ade t’orun

   Emi ‘gboya, k’agbara Re 

   Ran wa lowo nigba ‘danwo 

   Pa wa mo lailese.


3. Emi imo, to ese wa

   Li ona Re ti ko l’ewu 

   T’awon angel ‘ti rin 

   Nib i t’Iwo Oluto wa 

   Iwo Emi ifokansin 

   Mu wa sunm’Olorun.


4. Sunmo wa lojo aye wa 

   Emi iberu Olorun

   N’ikoko aya wa

   F‘owo t’o ye kun okan wa 

   Lati sin ife mimo Re

   T'o l'ododo julo.


5. Ma to wa lo l'alafia

   Sinu iye ainipekun

   K'a jere giga na

   K’a ja ogun aye wa yi

   Nipa agbara Re mimo

   K'a si ba Krist'joba. Amin

English »

Update Hymn