HYMN 817

O.t.H.C 264 8.7 (FE 853)
"Gba awon enia Re la" - Ps.28:9 
Tune: Baba wa orun, awa de1.  EMI ti nji oku dide

A wole niwaju Re

Na ‘wo Emi ‘ye Re si wa 

Ko so gbogbo wa d‘otun 

Omo Baba to d’enia 

Woli, Alufa, Oluwa.

Egbe: Olugbala, Olugbala 

Olugbala, gba wa la.


2.  Egbe Kerubu aiye yi

E se ara nyin lokan 

Egbe Serafu aiye yi

E fi okan kan sise

Ran wa lowo ka sise Re 

Ka mase se aseti.

Egbe: Olugbala...


3.  Ma sise l’oruko Jesu 

Mase wo awon elegan 

Si Matteu ori keta 

W‘ese kerindilogun 

Sokale ninu olanla 

Sarin Egbe Serafu.

Egbe: Olugbala...


4.  F’ojurere wo ‘dapo wa 

F‘oro mimo Re ye wa 

Fitila t’o ran sarin wa 

Ma ba wa b’ororo si 

Nigbat‘ ota ba sunmo wa 

Jesu, jowo sunmo wa.

Egbe: Olugbala...


5.  Okunkun yio b’oju orun 

Isele nla y’o sise

Awon irawo y’o ma ja 

Gegebi ojo ti nro

E ma jafara adura 

Gbogbo enyin enia mi.

Egbe: Olugbala...


6.  Nigbat’ o ba d’ojo kehin 

T’omo ko ni mo baba 

Ma doju ti wa l’ojo na 

Gba ‘awa Egbe Serafu 

Ran wa lowo ka sise Re 

K’a le ma ja f'otito.

Egbe: Olugbala...


7.  E f'oge fun Baba loke

E f'ogo fun Omo Re 

E f'ogo fun Emi Mimo 

Metalokan a juba

Ongbe re ma nghe okan wa 

Fi manna orun bo wa.

Egbe: Olugbala, Olugbala 

Olugbala, gba wa la.  Amin

English »

Update Hymn