HYMN 818

d.m.f.s.m.f.m.f.f.m.f.l.s:-
10s. (FE 854)
"Jesu pade won, O wipe, Alafia" - Matt.28:91. ALAFIA ni fun Egbe Mimo

   Ta da sile fun ‘gbega, Krist’l'Eko.


2. Alafia ni fun enikeni

   T’o n‘oruko nin‘ Egbe mimo yi.


3. Alafia ni fun awon wonni 

   T’o jeri Kristi de oju iku.


4. Alafia ni fun awon 

   T’o forit‘ iponju titi dopin.


5. Alafia ni fun awon wonni 

   T’o sise Kristi laiberu egba.


6. Alafia ni fun awon wonni

   T'a sa l'ami Kristi ninu aiye.


7. Alafia ni f'omo Egbe yi 

   Ade ogo ni y'o je ere re.


8. Egbe na nkun, o si ntankale lo, 

   Lagbara Kristi yio kan ka aiye.


9. Agba nla Kristi mbe f'egbe yi, 

   Ao le subu larin igbi aiye.


10. L‘enit'o nwa isubu Egbe yi 

    Mo p’o soro lati tapa segun.


11. Gbat’aiye at'ogo re ba dopin 

    Egbe yi yio wa lai lodo Oluwa.


12. Ko Halleluya s’Oba Olore 

    F’Egbe rere t’a gbe kale s’aiye. Amin

English »

Update Hymn