HYMN 823

(FE 860)
"Oluwa Olorun awon Omo-ogun
gbo adura mi" - Ps. 84:81. AGO re wonni ti ni)

   ewa to, Oluwa)

   Okan mi nfa si ‘le Olorun) - 2ce

   Tor'awon Eiye Orun

   nwon nile lor’ igi 

   Alapandede nwon nte ite o.

Egbe: Sugbon ibukun ni 
 
     F'awa Egbe Serafu

     Awa nile ile Ayo

     Lodo Oluwa

     Ibukun o, Halleluyah, 

     lbukun o,

     Ibukun o, Halleluyah, 

     ibukun o.


2. Okan mi nfa nitoto sile o) 

   S’agbala Oba mimo o) 

   Ngo ma lo lat' ipa de ‘pa titi o) 

   Ngo fi gunle s’ebute Ogo). - 2ce

Egbe: Sugbon ibukun ni...
 

3. Ojo kan ninu agbala Oluwa ) 

   O san ju egberun ojo lo)

   Ore-Ofe pelu ibukun je t'Olorun) - 2ce

   Ibukun ni f'eni to sin.

Egbe: Sugbon ibukun ni...


4. Mimo, Pipe, l'Obaluwaiye) 

   Mimo o)

   Angeli e wa ka jumo sin o) 

   Eni ba sin Erintunde) 

   titi d‘opin)

   Yio gba ade iye l’ebute ogo) - 2ce

Egbe: Sugbon ibukun ni 
 
     F'awa Egbe Serafu

     Awa nile ile Ayo

     Lodo Oluwa

     Ibukun o, Halleluyah, 

     lbukun o,

     Ibukun o, Halleluyah, 

     ibukun o. Amin

English »

Update Hymn