HYMN 824

(FE 861)
"Nitorina ki enyin ki o pe" - Matt.5:481. JEK' A l’ayo ninu Jesu 

   Oba Alayo ni Jesu 

   Enikeni ti ba r’ayo Re gba 

   Banuje re y'o si fo lo.


2. Wo sa gba Oruko Re gbo

   Ki o si tun gbekele

   Ko si m’adura to wa nin'eje Re 

   Banuje re y'o si fo lo.


3. Kerubu ati Serafu

   Wo ha tun nbanuje bi?

   Kristi nso fun o, ke Halleluyah 

   Banuje re y’o si fo 1o.


4. Esu lo ha nderu ba o?

   Oso tabi aje ni?

   Pe Oruko Jesu nigbagbogbo 

   Banuje re y‘o si fo lo.


5. K'a ni ife gbogbo aiye 

   Ki se s’omo egbe nikan

   Gbana adura re y’o si goke

   Banuje re y‘o si fo lo.


6. Gbogbo enyin eda aiye 

   Juba oruko Jesu

   Oruko yi to fun banuje re 

   Banuje re y’o si fo lo.


7. Ranti pe On l’Eni Yanu 

   Oba Oludamoran 

   Alagbara, Baba aiyeraiye 

   Alade Alafia.


8. A f’ogo fun Baba l’oke

   A f’ogo fun Omo Re

   Ogo ni fun Emi t’o ndari wa 

   Metalokan wa gb’ope wa. Amin

English »

Update Hymn