HYMN 829

t.s.s. 999 P.M (866)
"Nwon wipe Halleluyah" - Ifi. 19:3
Tune: Gbo Orin Eni Rapada1. A juba Re, Halleluyah 

   Halle, Halleluyah, 

   Olorun wa, enit' a nsin 

   Yio s’ayo wa di kikun.

Egbe: Ibi rere kan wa 

     Ayipada ko si 

     Ko s’oru af'osan titi 

     Serafu yio I’ayo.


2. Onigbagbo, e ji giri 

   Serafu ma nkede, 

   Aborisa nsise ‘yanu 

   Onigbagbo nk’ egan.

Egbe: Ibi rere kan wa... 


3. Opolopo ese l’o wa 

   Sugbon eyi t’o buru

   Ese Ese, S'EMI MlMO 

   Eyi ko ni ‘dariji.

Egbe: Ibi rere kan wa... 


4. Opo ‘danwo l’o wa l’aiye 

   Sugbon eyi t’o buru

   K’a ma l’owo, k’aisan dani 

   Jesu gbe wa leke.

Egbe: Ibi rere kan wa... 


5. Ko s’ere kan t’o wa l’aiye 

   Fun Egbe Serafu

   Enit’ o ba sise re ye

   Yio gb’ade nikehin.

Egbe: Ibi rere kan wa... 


6. Aladura ma jafara 

   Ariran so ‘bode

  Larin ota le wa laiye 

  Baba yio segun fun nyin.

Egbe: Ibi rere kan wa... 


7. Alairise, alailera

   E mase banuje 

   Olupese, Oluwosan 

   Ko ni fi nyin sile.

Egbe: Ibi rere kan wa... 


8. Ogo ni fun Baba l’oke 

   Ogo ni fun Omo

   Ogo ni fun Emi Mimo 

   Metalokan lailai.

Egbe: Ibi rere kan wa 

     Ayipada ko si 

     Ko s’oru af'osan titi 

     Serafu yio I’ayo. Amin

English »

Update Hymn