HYMN 83

(FE 100)
"Oluwa on Ii Olorun wa" - Ps 105:71. A DUPE lowo Olorun

   T'o da wa si d'oni

   T‘o je k‘emi tun emi ri,

   Ogo f’oruko Re.

Egbe: A dupe lowo Olorun

      T'o da emi wa si d'oni

      T’o je k'emi tun emi ri

      Ogo f'oruko Re.


2. Ise po n'ilu Osogbo

   T'ilesa ko ni so;

   Egbe Ondo ti mura tan

   Lati gbe Jesu ga.

Egbe: A dupe lowo Olorun...


3. Egbe Eko damure nyin,

   Lati besu jagun;

   Oko pon pupo n'ilu Oke,

   Tani yio lo ka?

Egbe: A dupe lowo Olorun...


4.  A ki Baba Aladura

   O ku afojuba

   Olori ti jagun fun Jesu,

   O si segun Esu.

Egbe: A dupe lowo Olorun...


5. Orin Halle, Halleluya

   L’awa y'o ko l‘orun

   Nigbat' a ba r'Olugbala,

   Ni ori ite Re.

Egbe: A dupe lowo Olorun... Amin

English »

Update Hymn