HYMN 832

8s 7s (FE 869)
“E f’ope fun Oluwa" - Ps. 136:1
Tune: Jesu Mo Gbagbelehu Mi1. A DUPE lowo Jehovah 

  Oba Onibu-ore 

  Fun isegun t’o se fun wa 

  Larin odun t’o koja. 

Egbe: Awa si njo, awa si nyo 

     Fun idasi wa oni

     Ayo kun okan wa loni 

     Ogo fun metalokan.


2. Ojo ayo l’oni fun wa 

   Awa si nse ‘sin oro 

   Kerubu ati Serafu 

   E jeki a jo yin Baba.

Egbe: Awa si njo...


3. Jesu Olori Egbe wa 

   jek’ a ri O l’arin wa 

   Awa f’iyin fun O loni 

   Fun idasi erni wa.

Egbe: Awa si njo...


4. Kerubu ati Serafu

   Awa l’ayanfe Omo 

   Fun Olorun Metalokan 

   Oba Awimayehun.

Egbe: Awa si njo...


5. Gbogbo aje t’o wa laiye 

   Agbara won ti wo mi 

  Ni agbara Metalokan 

  Awa y’o segun esu.

Egbe: Awa si njo...


6. Ojo aye wa nlo s‘opin 

   E jek‘a mura s'ise 

   Gbogbo ise t'awa yio se 

   Okan ki yio lo lasan.

Egbe: Awa si njo...


7. A ki baba Aladura 

   K‘Olorun ko bukun o 

   Ade Ogo y‘o je tire 

   L'Agbara Metalokan.

Egbe: Awa si njo, awa si nyo 

     Fun idasi wa oni

     Ayo kun okan wa loni 

     Ogo fun metalokan. Amin

English »

Update Hymn