HYMN 834

C.M.S 261 8.9.8.8 (FE 871) 
“Nwon fe ilu ti o dara ju”
- Heb.11:161. ANSORO ile ‘bukun ni,

   Ile didan at’ile ewa 

   ‘Gbagbogbo l’a nso t‘ogo re; 

   Y’o ti dun to lati de‘ be.


2. A nsoro ita wura re, 

   Oso odi re ti ko l’egbe 

   Faji re ko se fenu so 

   Y‘o ti dun to lati de ‘be.


3. A nso p‘ese ko si nibe 

   Ko s‘aniyan at‘ibanuje 

   Pelu ‘danwo lode, ninu 

   Y’o ti dun to lati de ‘be.


4. A nsoro orin iyin re,

   Ti a ko le f’orin aiye we;

   B' o ti wu k’orin wa dun to 

   Y’o ti dun to lati de ‘be.


5. A nsoro isin ife re

   Ti agbada t’awon mimo nwo 

   ljo akobi ti oke 

   Y’o ti dun to lati de be.


6. Jo, Oluwa, t’ibi t’ire

   Sa se emi wa ye fun orun; 

   Laipe. awa na yio mo,

   B'o ti dun to lati de ‘be. Amin

English »

Update Hymn