HYMN 836

7.6.7.6 D
Tune: Duro, duro fun Jesu1. EMI, okan at'ara 

   Jesu mo fi fun O 

   Fun ebo mimo lati 

   Ma je Tire titi

   Mo fi ara mi rubo

   Jesu Tire l'emi

   Ki ‘gbagbo mi mase ye 

   Se mi mi ni tire nikan.


2. Jesu, Olugbala nla 

   Mo gbeke mi le O 

   Mo wa igbala nla Re 

   Mo bere ‘leri Re

   Mo gba eya ara mi 

   Kuro labe ese

   Mo fi fun o b’ohun elo 

   Lati lo si segun.


3. Mo f’ise t’ara sile

   Ki nle wa lodo Re

   Jesu Olugbala mi 

   F‘emi Re sinu mi

   Tire li emi, Jesu

   T’a f'eje Re we mo 

   T’Emi ti ya si mimo 

   Ebo fun Olorun. Amin

English »

Update Hymn