HYMN 837

C.M.S 465 H.C 503 7s (FE 974)
“O gbe owo Re le won O si sure 
fun won" - Marku 10:161. JESU fe mi, mo mo be 

   Bibeli l‘o so fun mi

   Tire l‘awon omode 

   Nwon ko lagbara, On ni.


2. Jesu fe mi En’to ku 

   Lati si orun sile 

   Yio we ese mi nu 

   Jeki omo Re wole.


3. Jesu fe mi sibe si

   Bi emi tile s‘aisan 

   Lor'akete aisan ni 

   Y’o t‘ite Re wa so mi.


4. Jesu fe mi, y’o duro

   Ti mi ni gbogb’ona mi

   Gba mba f’aiye yi sile 

   Y’o mu mi re ‘le orun. Amin

English »

Update Hymn