HYMN 843

6 8s (FE 880) 
"E yin Oluwa lati aiye wa" - Ps.148:7
Tune: lgbagbo mi Duro Iori1. OLORUN Olodumare 

   Wo n’iyin on ope ye fun 

   Wo ti ngbe arin Kerubu 

   Ran tansan ife re si wa.

Egeb: Ogo, Ogo, f'Oba Olore 

      Iyin Re duro titi lai.


2. Olorun Mose Orimolade 
 
   A dupe fun lranlowo re 

   T'o f’idi Egbe Serafu sole 

   Lori Apat‘ayeraye.

Egeb: Ogo, Ogo...


3. Gba ‘yonu de b’awosanma 

   T‘o su dudu t’o nsan ara 

   O duro ti wa larin re

   O si mu wa bori dandan.

Egeb: Ogo, Ogo...


4. Ogun ota dide si wa

   Aiye on esu ndena wa

   O mu wa la gbogbo re koja 

   Ogo, iyin f’Oruko Re.

Egeb: Ogo, Ogo...


5. Obangiji, Alaranse Eda 

   Pa wa mo n'nu igbi aiye 

   K'alafia ipese, ibukun 

   Je ti wa I‘ojo aiye wa.

Egeb: Ogo, Ogo...


6. JAH-JEHOVAH NISSI Oba wa, 

   lwo ni Oba Olusegun

   Masai f 'isegun fun Alagba wa, 

   Fun Baba Aladura wa.

Egeb: Ogo, Ogo...


7. Olorun Mose Orimolade 

   Gba iyin ati ope wa

   Ka le yo titi niwaju Re 

   L’oke orun l'ojo ‘kehin.

Egeb: Ogo, Ogo, f'Oba Olore 

      Iyin Re duro titi lai. Amin

English »

Update Hymn