HYMN 845

D. 7s 6s (FE 883) 
“Ni bibi emi o mu iru omo re bi si"
- Gen. 16:10
Tune: A Roke A furugbin1. OLORUN to fe Abraham 

   To fi se ore re

   Pe ni 'ru omo re laiye

   Yio dabi irawo

   O fi Isaaki seleri

   Lati gba ile na

   O mu ileri na se fun.

   Jakobu omo re.

Egbe: K'a damure lati jagun - 2ce 

     K'a damure e, - 2ce

     K'a damure lati jagun.


2. Iwo to gbo ti Mosisi 

   Lori oke Sinai

   Iwo to pe Samueli 

   Nigbat‘ o wa lewe 

   Iwo to pelu Dafidi 

   T'o segun Golayat 
 
   E wa di Egbe Serafu

   Lamure ododo.

Egbe: K'a damure...


3. Gbo ti Jesu Oluwa wa 

   Ti se ileri fun

   Awon Aposteli gbani 

   Lari j‘alagbara

   Nigba nwon gba Emi Mimo 

   Nwon fi ayo sise

   Irapada d'orin fun won

   Titi d’oke orun.

Egbe: K'a damure...


4. Kerubu ati Serafu 

   E damure giri

   Ki Egbe Aladura 

   Mura lati sise 

   Ileri ti Oluwa se 

   Nipa ti otito

   K’a ranti a o segun

   Ni ojo ikehin.

Egbe: K'a damure...


5. Enyin eni irapada 

   E korin igbala

   Si eni ti o fe wa 

   To f‘eje Re ra wa 

   Lati oko eru wa 

   Lo si ile Kenaani, 

   Ilu Jerusalemu 

   Lodo Jesu Oba.

Egbe: K'a damure...


6. Eni to ran Mose lowo 

   Baba Aladura

   Lati se ise Alakoso 

   Serafu, Kerubu

   Fi ‘segun fun de isegun 

   Lati ja ajaye

   Lati gba ade Ogo na 

   B’awon Woli saju.

Egbe: K'a damure lati jagun - 2ce 

     K'a damure e, - 2ce

     K'a damure lati jagun. Amin

English »

Update Hymn