HYMN 846

6666
“Ko mi li ona Re, Oluwa” - OD.27:11
Tune: Jesu oro Re ye1. ONA Re, Oluwa

   B’o ti wu ko ha to! 

   Fi owo Re to mi 

   Yan ipa mi fun mi.


2. B’o rorun b’o soro 

   Daradara lo je

   B’o wo, b’o to tara

   Lodo Re l’opin si.


3. Nko gbodo yan ‘pin mi 

   Nko tile je yan an

   Yan fun mi Olorun

   Ki mba le rin dede.


4. Ijoba ti mo nwa 

   Tire ni, jek‘ ona 

   T’o re ‘be je Tire 

   Bi beko un o sina.


5. Gba ago mi, f’ayo

   Tab’ibanuje kun

   B’o ti to l’oju Re

   Yan ‘re tab’ibi mi.


6. Yiyan ki se temi

   Ninu ohunkohun

   Iwo s’Oluto mi

   Ogbon, ohun gbogbo. Amin

English »

Update Hymn