HYMN 848

(FE 889)1. ERO s’orun l’awa nse 

   Aiye l’ajo orun n’ile wa 

   Atipo ni awa je o

   Aiye l'ajo, orun n’ile wa 

  Gbogbo ewu lo duro o 

  Yika wa l’ojo gbogbo 

  Ekun l’oni, erin l'ola 

  Aiye l’ajo, orun n’ile wa.


2. Iranse ti sun n’nu Oluwa 

   Aiye l’ajo, orun n‘ile wa 

  lse d'opin, ija d’opin 

  Aiye l’ajo, orun n’ile wa 

  O ti jagun f'Oluwa

  O bo s‘ayo Baba re

  Titi lao se ‘ranti re

  Aiye l‘ajo orun n’ile wa.


3. Omode, nku, agba nku o 

   Aiye l'ajo orun n’ile wa 

   K’a ku n‘nu Jesu lo dara, 

  Aiye l’ajo orun n’ile wa 

  Ka lo ‘gba wa fun Jesu 

  Tori ojo iku mbe

  Ko s'eniti ko ni ku o 

  Aiye l’ajo orun n’ile wa.


4. Lod‘Oluwa ni ‘simi mbe 

   Aiye l’ajo orun n’ile wa 

  Banuje kan ko si nibe 

  Aiye l'ajo orun n’ile wa 

  Opo ibugbe lo wa 

  T'Olorun ti ko s'orun 

  F’awon to ba sin I dopin 

  Aiye l’ajo orun n’ile wa.


5. lranse ma yo n'nu Oluwa 

   Aiye l‘ajo orun n'ile wa 

  O ti ri Jesu to fe o

  Aiye l’ajo orun n’ile wa 

  Baba rere toju wa 

  K'aiye mase gbe wa lo! 

  K‘a le j’eni idalare

  Aiye l’ajo orun n’ile wa. Amin

English »

Update Hymn