HYMN 850

D.S.M (FE 891) 
Tune: Olorun Serafu1. EGBE awon angeli 

   Egbe ogun orun

   Egbe awon Aposteli 
 
   Awon Eni-Mimo 

   Gbogbo won loke orun 

   Nyin O tosan-toru 

   Olorun Metalokan wa

   Oga-Ogo julo.


2. Legbegbe l’awa pejo 

   Niwaju Re, Baba 

   Lati fi ope wa fun O 

   Pel’ awon ore wa 

   Ope ‘kore l‘a mu wa 

   F‘Oluwa ikore 

   Olorun, jo sokale wa 

   F’ogo Re kun ‘le yi.


3. Larin ainiye ibi 

   T'o rogba yi wa ka 

   Larin ayida aiye yi 

   Lehin ‘kore esi 

   Awa f’ope fun O

   N'tori ‘Wo da wa si 

   Loni, odun ikore wa 

   A f‘ogo f’Oko Re.


4. Gba Noa rubo ope 

   Wo f'osumare han

   Ami wi pe kikun omi 

   Ki o bo aiye mo 

   Baba f’osumare han 

   Nitori Jesu wa

   K’iponju on ibanuje 

   Mase tun de da wa.


5. Obinrin opo ‘gbani 

   Ko ri pupo mu wa 

   Sugbon o ri ibukun gba 

   Fun iwon ti o le se 

   Jesu, yin wa loni 

   Je k’a ri ‘bukun gba 

   Tewogba ore ope wa 

   B’otile s’alaiye.


6. Awa mbe O, Olorun

  Gba okan wa pelu

  Okan ese wa la mu wa 

  Egbin po ninu re

  F‘Eje Re mimo Jesu 

  We abawon re nu

  Ki okan ati ore wa 

  J’ebo ope fun o. Amin

English »

Update Hymn