HYMN 856

7.6.7.6 D
Tune: Duro, Duro fun Jesu


1. ‘GBATI ‘danwo yi mi ka

   Odo Krist’ ni mo nlo 

   Ni okan aya Re ni

   Ibi isadi mi

   Mo s‘okan mi paya fun 

   O mo gbogb’ edun mi 

   Bi mo ti nso nkan wonyi 

   O m’edun mi kuro.


2. ‘Gbati mo kun fun eru

   Ti mo nsukun pere

   O tan ibanuje mi 

   O le eru mi lo

   O r'ewu t’o yi mi ka 

   Ati ailera mi

   O fun mi l’ohun ija 

   Lati segun ese.


3. L’odo Kristi ni un o lo 

   Nibi t’o wu ko je

   Un o sa ma wo oju Re 

   O daju pe un o ri

   ‘Gb’ayo tabi ‘banuje 

   Ohun to wu ko je

   Odo Re sa ni un o lo

   Oun y’o o si to mi wa. Amin

English »

Update Hymn