HYMN 857

8.8.8 D1. MASE beru ‘wo okan mi 

   Eleda mi ni nma foya 

   Oluwa pe mi l’oruko

   O ndabobo, ko si jinna 

   Eje Re ti s‘etu fun mi

   O nfe, O si nto mi sibe.


2. ‘Gba mo nkoja larin ibu 

   Mo f’igbagbo toro 'ranwo 

   Igbi si duro l’okere

   Won bi kuro Ii ori mi

   Emi ko beru ipa won

   Ko si ewu, Olorun mbe.


3. Mo yi oju igbagbo s’i 

   Mo ntesiwaju larin ‘na 

   Ina gbagbe lati jo mi 

   Owo ina njo yi mi ka 

   Mo jewo agbar’ami na 

   Mo ke pe" Temi ni Jesu.


4. Olugbala, duro ti mi 

   Dabobo mi nigba ‘danwo 

   Pa mi mo ni ikawo Re 

   F’agbara ‘gbala han n’nu mi 

   Ki apa Re je abo mi

   Ko s'ohun le ja mi kuro.


5. B'O si ti pe mi pe ki nwa 

   Wo Olore ti ngba ni la

   Un o rin lori okun ti nja 

   Igbi yo gbe ese mi ro 

   Nki yo beru isan na 

   Bi o ti wu ki o le to.


6. Gbat‘okunkun b’oju orun 

   T’igbi ‘banuje yi mi ka 

   T‘iji ibinu ru soke

   To fere bori okan mi

   Emi mi yo ri dake je

   Y’o gb‘ohun jeje pe, 'simi.


7. Bi mo wa n‘nu eru ‘ponju 

   Laisewu un o sete iku

   B’ese doju ija ko mi

   Ti esu gbe ogun ti mi 

   B’igbo Mose, un o ma gberu 

   Ina ki o pa mi lara. Amin

English »

Update Hymn