HYMN 859

CM1. OLORUN, ‘ranwo eni Re 

   Reti wa n‘igba bi

   A gba ‘Wo Eni Airi gbo 

   Awa nwa O sibe.


2. Ese ti awon elese 

   Nfojudi ipa Re

   Ti won si nhale b'enipe 

   ‘Wo ko ri ese won.


3. Oluwa, dide k'o gba wa 

   A m'oran wa t'O wa

   F‘ododo at'ipa joba

   Wo nikan Ii Oba.


4. Iwo mo gbogbo ife wa 

   ‘Ranwo Re wa n‘tosi 

   Pese okan wa f'adura 

   Si gba adura wa. Amin

English »

Update Hymn