HYMN 86

C.M.S 427 H.C. 429. 8s 4 (FE 103)
“Ohun owo Re Ii awa ti fi fun O"
- 1 Kron. 29:141. OLUWA orun on aiye

   Wo n‘iyin at’ope ye fun

   Bawo l‘a ba ti fe O to?

   Onibu‐Ore.


2. Orun ti nran at’afefe

   Gbogbo eweko nso ‘fe Re;

   ‘Wo l’O nmu irugbin dara,

   Onibu-Ore.


3. Fun ara lile wa gbogbo

   Fun gbogbo ibukun aiye,

   Awa yin O, a si dupe,

   Onibu-Ore.


4. O ko du wa li Omo Re,

   O fi fun aiye ese wa,

   O si f’ebun gbogbo pelu;

   Onibu‐Ore.


5. O fun wa l’Emi Mimo Re,

   Emi iye at’agbara

   O rojo ekun ‘bukun Re,

   Le wa lori.


6. Fun idariji ese wa,

   Ati fun ireti orun,

   Kil’ohun t’a ba fi fun O?

   Onibu-Ore.


7. Owo, ti a nna, ofo ni,

   Sugbon eyit’a fi fun O,

   O je isura tit’ aiye

   Onibu-Ore.


8. Ohun t’a bun O, Oluwa,

   ‘Wo o san le a pade fun wa

   Layo l'a o ta O lore

   Onibu-Ore.


9. Ni odo Re l’a ti san wa,

   Olorun Olodumare;

   Jek' a le ba O gbe titi

   Onibu-Ore. Amin

English »

Update Hymn