HYMN 860

8.7.8.7. D
Tune: Oba ti ki ye majemu1. B‘O ti dun lati gba Jesu

   Gbo gegebi oro Re

   K’a simi lor’ileri Re 

   Sa gbagbo l’Oluwa wi.

Egbe: Jesu, Jesu, emi gbagbo 

     Mo gbekele n’gbagbogbo 

     Jesu, Jesu, Alabukun

     Ki nle gbekele O si.


2. B‘o ti dun lati gba Jesu 

   K’a gb’eje wenumo Re 

   Igbagbo ni ki a fi bo 

   Sin’eje wenumo na.


Egbe: Jesu, Jesu...


3. B’o ti dun lati gba Jesu 

   Ki nk’ara ese sile

   Ki ngb’ayo, iye, isimi 

   Lati odo Jesu mi.

Egbe: Jesu, Jesu...


4. Mo yo mo gbeke mi le O

   Jesu mi, Alabukun

   Mo mo pe O wa pelu mi

   Ntoju mi titi dopin.

Egbe: Jesu, Jesu, emi gbagbo 

     Mo gbekele n’gbagbogbo 

     Jesu, Jesu, Alabukun

     Ki nle gbekele O si. Amin

English »

Update Hymn