HYMN 861

OMO EGBE SERAFU DIDE1. OMO Egbe Serafu dide 

   F'ife at'aniyan dide

   Jeki imole re tan roro 

   Dide lati gbe Jesu ga.

Egbe: Ma yan nin'ola Olorun wa 

     Ma yan nin'oIa Olarun wa 

     Ma yan, ma yan

     Ma rin, ma yan n'nu ‘fe Jesu.


2. Omo Egbe Serafu dide 

   F'ayo ru agbelebu re

   Ma binuje, ma b’ohun bo

   Jesu y’o s’ekun re d’ayo.

Egbe: Ma yan nin'ola...


3. Omo Egbe Serafu dide 

   Ireti re ko ni saki

   Baba ko ni ko ohun re 

   Mase je ko re ‘gbagbo re.

Egbe: Ma yan nin'ola...


4. Omo Egbe Serafu dide 

   Oke nla yio di petele 

   Bi Olorun ba nse tiwa 

   Tani le doju ‘jako wa.

Egbe: Ma yan nin'ola...


5. Omo Egbe Serafu dide 

   Jesu Oluwa fere de 

   Ade ‘rawo yio je tiwa 

   Larin Egbe Mimo t‘orun.

Egbe: Ma yan nin'ola Olorun wa 

     Ma yan nin'oIa Olarun wa 

     Ma yan, ma yan

     Ma rin, ma yan n'nu ‘fe Jesu. Amin

English »

Update Hymn