HYMN 89

1. OLORUN mi, ‘gba ti mo f'eru ‘yanu

   Kiyesi ise ti owo re se

   Mo ri ‘rawo, mo gb’ohun

   aara rti nsan

   Agbara re tan ka gbogbo aye.

Egbe: Okan mi ko ‘rin si

      Oluwa re

      Alagbara I’Olorun mi!

      Okan mi ko ‘rin si

      Oluwa re

      Alagbara l'OIorun mi.


2. ‘Gba ti mo rin kaakiri ninu igbo

   Mo gbo t’awon eye n ko ‘rin didun

   ‘Gba mo wo ‘le lat’ ori oke giga

   T’odo n san, t’afefe si fe si mi

Egbe: Okan mi ko ‘rin si...


3. ‘Gba ti mo ro o pe ko da Omo re si

   Lati wa ku, mo roju gba a gbo pe

   O r'eru ese mi lo lori igi

   O t’eje Re sile, O ku fun mi.

Egbe: Okan mi ko ‘rin si...


4. ‘Gba Kristi yoo de pelu orin ‘segun

   Wa mu mi lo, ayo yoo gb‘okan mi!

   'Gba naa ngo juba, ngo f’irele wole

   Ngo kede ‘titobi I'Olorun mi!.

Egbe: Okan mi ko ‘rin si... Amin

English »

Update Hymn