HYMN 9

C.M.S 17, H.C 25, L.M (FE 26)
"Nigbati o si di asale, ti orun wo, nwon
ko gbogbo awon olokunrun 
to o wa" - Marku 1:32


1. L'OJU ale, ‘gbat’ orun wo,

   Nwon gbe abirun w'odo Re; 

   Oniruru ni aisan won,

   Sugbon nwon f‘ayo lo le won.


2. Jesu a de loj’ ale yi,

   A sunmo O t’awa t'arun wa, 

   Bi a ko tile le ri O,

   Sugbon a mo p’O sunmo wa


3. Olugbala, wo osi wa, 

   Omi ko san, ‘mi banuje 

   Omi ko ni ife si O,

   Ife elomi si tutu.


4. Omi mo pe asan l'aiye 

   Beni nwon ko f'aiye sile 

   Omi l'ore ti ko se ‘re 

   Beni nwon ko fi O s‘ore.


5. Ko s’okan ninu wa t'o pe 

   Gbogbpo wa si ni elese 

   Awon t’o si nsin O toto 

   Mo ara won ni alaipe.


6. Sugbon Jesu Olugbala 

   Eni bi awa ni Iwo se 

   ‘Wo ti ri danwo bi awa 

   'Wo si ti mo ailera wa.


7. Agbar‘owo Re wa sibe

   Ore Re si ni Agbara,

   Gbo adura ale wa yi,

   Ni anu, wo gbogbo wa san. Amin

English »

Update Hymn