HYMN 95

(FE 112)
"Efi ope fun Oluwa" - Ps. 105:11. EJE ka jumo f’ope f'Olorun

   Orin iyin, at'ope lo ye wa,

   Iyanu n'ife Re si gbogbo wa,

   E korin ‘yin s’Oba Olore wa.

Egbe: Halleluyah Ogo ni fun Baba

      A f'ijo, ilu yin Olorun wa,

      Alaye ni o yin O, bo ti ye

      Halleluya! Ogo ni fun Baba.


2. Kil‘ a fi san j’awon t'iku ti pa?

   Iwo lo f’owo wo wa di oni

   ‘Wo lo nso wa to ngba wa lo'ewu

   E korin 'yin s'Olutoju wa.

Egbe: Halleluyah Ogo...


3. Gbogbo alaye I'O nfun l'onje won,

   Iwo lo npese f‘onikaluku;

   Iwo lo nsike eda Re gbogbo

   E korin ‘yin si Oni bu‐Ore.

Egbe: Halleluyah Ogo...


4. Ohun wa ko dun to lati korin

   Enu wa ko gboro to fun ope

   B'awa n'egberun ahon nikokan

   Nwon kere ju lati gb’ola Re ga.

Egbe: Halleluyah Ogo...


5. Gbe wa leke ‘soro l‘ojo gbogbo

   Fun wa l'ayo at'alafia Re,

   Je k'a ri bukun gba lo ‘le wa,

   K'a ba le wa f'ogo f’oruko Re.

Egbe: Halleluyah Ogo...


6. Enyin Angeli l‘orun wa ba wa gbe

   Orin iyin at’ope t'o ye wa

   S'Oba wa aiku Olola-julo

   Oba wa Jehofa t'o joba.

Egbe: Halleluyah Ogo... Amin

English »

Update Hymn