HYMN 99

(FE 116)
“Jeki awon enia ki o yin O, Olorun"
- Ps. 67:31. ENYlN Egbe Serafu,

   Ati Egbe Kerubu

   E fi ope fun Olorun,

   T'o d’emi wa si d’oni.

Egbe: Emi ko Ie sai sope
     
      Emi ko Ie sai sope

      Ore t’Olorun se fun mi,

      Emi ko Ie sai sope.


2. Loto l'esu gbogun

   Sugbon ko le segun

   Lagbara Metalokan wa,

   Awa yio bori re.

Egbe: Emi ko Ie sai sope...


3. Elomiran ti ku,

   Elomiran w’ewon

   Elomiran nrin ni ile

   Ti moto ti te pa.

Egbe: Emi ko Ie sai sope...


4. Ope ni f'Olorun,

   F'anu Re l'Ori wa,

   O gbo tire, O gbo temi,

   Ogo ni f'Olorun.

Egbe: Emi ko Ie sai sope...


5. Olorun alanu,

   Siju anu wo wa,

   Jowo pese fun aini wa,

   K'ile r'oju fun wa.

Egbe: Emi ko Ie sai sope...


6. F'ilera f‘alaisan

   Jesu Olugbala

   Jeki awon alaisan,

   Ri ‘wosan lodo Re.

Egbe: Emi ko Ie sai sope...


7. Mu ile ri re ese

   Jehovah Tabbikubb,

   K'awon afoju le riran

   K‘alailera k’o san.

Egbe: Emi ko Ie sai sope...


8. Opo ti sako lo

   Nwon ko si mona mo

   Elomiran j'asiwaju

   Sugbon o fa s‘ehin.

Egbe: Emi ko Ie sai sope...


9. Jehovah-Jire wa,

   Pese fun aini wa,

   Pese omo f‘awon agan

   Jek' a ri ‘bukun gba.

Egbe: Emi ko Ie sai sope...


10. Olorun alanu

    Dariji eda Re;

    Mase f’ese bi araiye

    Jeki ojo k'o ro.

Egbe: Emi ko Ie sai sope...


11. F'ibukun Re f‘Oba

    At'awon Igbimo

    F'alafia fun ilu wa

    K’a ma rogun adaja.

Egbe: Emi ko Ie sai sope...


12. E f'ogo fun Baba

    E f'Ogo fun Omo

    E f'ogo fun Emi Mimo

    Metalokan lailai.

Egbe: Emi ko Ie sai sope... Amin

English »

Update Hymn