HYMN 100

1. EMI Baba Alaye

   Sokale pelu

   Agbara Pentikosti

   So okan wa ji

   Ki O si mu gbona

   B'ina orun nla

   Pelu ‘tunu nla

   Tan ‘mole re.


2. Aye ati emi wa

   Gba, fi se Tire

   Ninu isin wa fun O

   Ka ni ‘ranwo Re

   Lati j'olotito

   K’ebun at‘orun

   Ti Pentikosti

   Ba s'ori wa.


3. Fi eje ‘yebiye Re

   T'oke Kalfari
 
   We okan ese wa nu

   Si ra wa pada

   Fi ‘fe kun aya wa

   Ka rin ‘na oto

   lfe Re lao se

   Bi ti orun.


4. Baba, Omo on Emi

   Metalokan lae

   lyin, Ogo, agbara

   Je Tire nikan

   Ewa Re l'aye yi

   Yo je ayo wa

   Pelu idupe

   Aleluya! Amin.

English »

Update Hymn