HYMN 103

(FE 120)
Tune: Lo Kede Ayo Na.1. OLUWA l’Olus‘agutan mi,

   Emi k’o salani

   O mu mi dubule ‘nu papa oko,

   Tutu minimini.

Egbe: Awa dupe, at’ope da,

      Fun idasi Re fun wa

      Larin Egbe Serafu.


2. O mu mi lo si iha omi,

   Idake roro si de,

   O si tu okan mi lara,

   Ni ipa oruko Re.

Egbe: Awa dupe...


3. Nitoto bi mo tile nrin

   Larin afonifoji

   Emi ki yio beru ibi kan

   Nitori o wa pelu mi.

Egbe: Awa dupe...


4. Ogo Re ati opa Re

   Nwon si ntu mi ninu

   lwo te tabili onje sile

   Ni iwaju mi.

Egbe: Awa dupe...


5. Nitoto ire ati anu

   Ni yio ma to mi lehin

   Emi o gbekele Oluwa

   Ni gbogbo ojo aiye mi.

Egbe: Awa dupe...


6. K'a f'ogo fun Baba wa loke

   K'a f'ogo fun Omo Re

   K‘a f‘ogo fun O Emi Mimo

   Metalokan l'ope ye.

Egbe: Awa dupe... Amin

English »

Update Hymn