HYMN 109

(FE 126) Ki a fi ope fun Oluwa
Tune: K’a fi ope fun Olorun wa1. K'A fi ope fun Oluwa

   fun gbogbo opo anu Re

   K'a wa di ihamora wa

   Lati b’esu jagun.
 
Egbe: Esu n’ipe sugbon a o segun

      Ni agbara metalokan

      Ileri ti Oluwa se

      Y‘o wa sibe titi.


2. Gbogbo aiye e ho f’ayo

   Ki gbogbo wa si kun fun ‘se

   Ki aja titi de opin

   K’a si fi ‘da le le.

Egbe: Lese Kristi omo Baba

      Ni ibi awon Angeli nyo

      K’a be won yin Baba loke

      Omo, Emi lailai.


3. Awa omo egbe Serafu

   A fi ogo fun Oluwa

   T’o je k’emi tun ri emi

   Ogo f ’oruko Re.

Egbe: Gb 'oju s 'oke wo asia,

      Fun gbogbo awon t'o segun

      Enyin ara e ku abo,

      Ki Baba pelu nyin.


4. Awon t’o ti segun saju

   Nwon nwo wa bi awa ti nja

   Nwon si nfi ohun kan wipe

   Ara ma jafara.

Egbe: Nitor’ akoko die loku

      Ti aiye yi yio koja lo

      Bi asegun o daju pe,

      A o gb’a ade iye.


5. Awa si tun ki asaju wa,

   Ati awon ‘mo ogun re,

   Ara e ku ise emi,

   K'a gb’owo lowo ara wa.

Egbe: E ku abo, enyin ku iIe

      K'Olorun pelu gbogbo wa,

      K'o si fi ade ogo Re,

      De gbogbo wa lori.


6. Ope ni fun Metalokan

   T'o ba wa fo ‘tegun esu,

   Halleluyah‘s Olorun wa,

   Oju ti Lusifa.

Egbe: Ara e jo pelu ayo,

      Ara e gbe ohun s'oke

      Ki Baba fun wa ni fe Re.

      Eyi ti ko l’egbe. Amin

English »

Update Hymn