HYMN 111

C.M.S 550 t.H.C.54 L.M (FE 128)
"E fi yin fun Oluwa" Ps. 146:11. EJE k’a yin Olorun wa, 

   Enit' O wa l’oke orun

   T'O fi onje fun enia 

   Ti O si fi fun eranko.


2. O si te oju orun lo

   O da orun on osupa,

   lse owo Re n‘irawo 

   lye won awa ko le ka.


3. O si da ara enia,

   O si fun won lemi pelu 

   O si da ni daradara,

   Bi o ti ye, bi ba ti wa.


4. Sugbon enia dibaje 

   Nwon si bo sinu buburu 

   Ere ese ni nwon si nje 

   Ni wahala ati n’iku.


5. Sugbon je ka yin Olorun

   On fun wa ni Kristi Jesu

   Lati wa awon t'o ti nu

   Ninu ese ti nwon ti nrin. Amin

English »

Update Hymn