HYMN 115

C.M.S.556. H.C.564 C.M (FE 132) 
“Kili emi o fi fun Oluwa, nitori 
gbogbo ore Re si mi?" - Ps. 116:121. FUN anu to po b'iyanrin 

Ti mo ngba l’ojumo

Lat' odo Jesu Oluwa

Ki emi o fi fun?


2. Kini ngo fi fun Oluwa 

Lat‘ inu okan mi

Ese ti ba gbogbo re je 

Ko tile ja mo nkan.


3. Eyi l'ohun t'emi o se 

F'ohun to se fun mi 

Em' o mu ago igbala 

Ngo kepe Olorun.


4. Eyi l‘ope ti mo le da 

Emi osi, are

Em' o ma soro ebun Re,

Ngo si ma bere si.


5. Emi ko le sin b'o ti to 

   N ko n'ise kan to pe;

   Sugbon em'o sogo yi pe,

   'Gbese ope mi po. Amin

English »

Update Hymn