HYMN 116

H.C. 565, C.M (FE 133)
"Emi mi si yo si Olorun
Olugbala mi" - Luku1:47


1. EMI ba n‘egberun ahon

   Fun ‘yin Olugbala

   Ogo Olorun, Oba mi,

   lsegun Ore Re.


2. Jesu t'O s’eru wa d'ayo 

   T’o mu banuje tan

   Orin ni l'eti elese

   lye at'ilera.


3. O segun agbara ese, 

   O da onde sile

   Eje Re Ie w'eleri mo, 

   Eje Re seun fun mi.


4. O soro oku gb‘ohun Re 

   O gba emi titun 

   Onirobinuje y'ayo 

   Otosi si gba gbo.


5. Odi, e korin iyin Re, 

   Aditi, gb'ohun Re 

   Afoju, Olugbala de, 

   Ayaro, fo f'ayo.


6. Baba mi at'Olorun mi, 

   Fun mi n‘iranwo Re

   Ki nle ro ka gbogbo aiye 

   Ola Oruko Re. Amin

English »

Update Hymn