HYMN 120

C.M.S.239, t.H.C 222, L.M (FE 137)
"Emi o so ti iseun ife Oluwa" - Isa. 63:71. JI, Okan mi, dide layo

   Korin iyin Olugbala

   Ola Re bere orin mi 

   Seun ife Re ti po to!


2. O ri mo segbe n’isubu 

   Sibe, O fe mi l‘afetan 

   O yo mi ninu osi mi, 

   Seun ‘fe Re ti tobi to!


3. Ogun ota dide si mi

   Aiye at‘Esu ndena mi

   On nmu mi la gbogbo re ja 

   ‘Seun ‘fe Re to n’ ipa to!


4. Gba ‘yonu de, ba'awosanma, 

   T‘o su dudu t‘o nsa ara

   O duro ti mi larin re:

   ‘Seun ‘fe Re to dara to!


5. ‘Gbagbogbo l’okan ese mi 

   Nfe ya Iehin Oluwa mi; 

   Sugbon bi mo ti ngbagbe Re, 

   lseun ife Re ki ye.


6. Mo fere f‘aiye sile na, 

   Mo fe bo low'ara iku;

   A! k’emi ‘kehin mi korin 

   lseun lfe Re n’iku.


7. Nje ki nfo lo, ki nsi goke 

   S‘aiye imole titi lai;

   Ki nf’ayo iyanu korin 

   lseun ife Re lorun. Amin

English »

Update Hymn