HYMN 126

6.8s (FE 143)1. OLORUN ailopin, Iwo

   L'a f‘iyin atokan wa fun 

   Gbogbo ‘se Re l’aiye yin O 

   A juba Re, Oluwa wa, 

   Baba aiyeraiye, jeki

   Okan wa wole n’ite Re.


2. Awon angel' nkorin yin O 

   Balogun, Oba ‘won Oba, 

   Kikan l’awon Kerubu nyin 

   Seraf’ si nyin Metalokan; 

   Nwon nko, Mimo mimo, mimo 

   Orun, aiye, kun f'ogo Re!


3. Olorun awon baba wa 

   Awon Woli ti rohin Re 

   Egbe Aposteli rere,

   Nwon mbe l'ayo ati ogo 

   Woli ati awon mimo 

   Dapo lati gb'ola Re ga.


4. Olor' awon ajeriku,

   Nwon nf'oto sogo ninu Re, 

   Ijo gbe ohun re soke

   Yin Eleda gbogbo aiye
   
   Nwon si mba ‘won t‘o y‘ite ka, 

   Korin jinle Metalokan.


5. Baba Olola ailopin,

   Tire l'agbara at‘ife

   A juba Omo Re owon

   T‘o mbe n'nu ogo pelu Re, 

   At‘Olorun Emi Mimo, 

   Olutunu aiyeraiye. Amin

English »

Update Hymn