HYMN 127

10s (FE 144)
Tune: Wa ba mi gbe.1. A f’ope f’Olorun t'O da wa 

   Ti O nbo t’O si nsike wa,

   On li Oluwa ti o le bukun wa, 

   E je k‘a jo korin s’Eleda wa.


2. A dupe f‘ona t‘o pe wa si,

   Sinu oko ‘gbala kehin,

   Ran wa lowo k’a le fi iwa wa jo, 

   Awon Egbe mimo Seraf' t’oke.


3. A dupe fun okun, ilera,

   Ti O nfifun awa omo Re, 

   Enyin l’Olorun ti ko je k’o re wa, 

   A dupe a yin O Olore wa.


4. A dupe pe O ngbadura wa, 

   Ni ona gbogbo t'a npe O si 

   Papa nigbati esu nfe ta ‘fa re 

   E ke Halleluyah’s Olusegun.


5. A dupe f’alafia ara,

   T’o nfun wa, t‘o si nje k'a mo O,

   Pe' wo l’Olorun t’o le s‘ohun gbogbo 

   A dupe a yin Oba Olore.


6. A dupe f’Emi t‘o ndari wa,

   ‘Gbat' awon omo Re nfe sako

   O nf‘ ohun kele e pe wa pada s’agbo 

   Metalokan Mimo a juba Re.


7. A dupe p'a mo ojubo Re,

   Larin hilahilo aiye yi

   O nje k‘a mo pe Iwo ni Baba wa, 

   Ayo Ayo, ayo ani Baba.


8. Ope l’o ye Olodumare,

   Fun didasi ti O nda wa si

   T’O nbo t’O si nkosi wa, lojojumo 

   Ope, ope iyin f 'Olore wa.


9. A dupe fun O, Eleda wa, 

   Fun ise Re t’ O nse larin wa, 

   Ti O ko fi wa sile ni seju kan 

   Ogo, Ola iyin s‘Eleda wa.


10. Olorun Eleda Serafu

    Ti aginju aiye wa yi

    gb'ohun wa k’o si ma lo nigbagbogbo 

    K'a le b'awon Serafu t'orun korin.


11. Baba wa joko k’o gb’ope wa 

    L’arin egbe egbe mimo Serafu 

    Ohun ope ni k’O ma fi s’arin wa, 

    Titi a o fi de ‘le Paradise. Amin

English »

Update Hymn