HYMN 137

H.C.563. 11.11.11.(FE 154)
"Li oruko Jesu, ki gbogbo ekun ma
Wole” - Filipi 2:101. L’OKO Jesu, gbogbo ekun yio wole 

   Ahon yio jewo Re pe On l’Oba ogo 

   lfe Baba ni pe, k’a pe l'Oluwa 

   Enit'ise Oro lat‘aiyeraiye.


2. Nipa Oro Re l’a da ohun gbogbo 

   Awon angel at’awon imole,

   lte, Ijoba, at'awon irawo 

   Gbogbo eda orun ninu ogun won.


3. O re ra Re sile, lati gb’oruko 

   Lodo awon elese t'o o wa ku fun,

   Ko je ki egan ba le oruko yi, 

   Titi O fi jinde t’a si se l’ogo.


4. Oruko yi lo f’ayo gbe lo s’orun 

   Koja gbogbo eda lo sibi giga 

   S'ite Olorun, sokan aiya Baba 

   O si ti ogo simi pipe kun.


5. F’ife daruko Re, enyin ara wa, 

   Pelu eru jeje ati iyanu

   Olorun Oluwa, Krist’ Olugbala, 

   Titi lao ma sin O, ao ma teriba.


6. E je ki Jesu joba n’nu okan nyin 

   Y’o mu ohun buburu gbogbo kuro 

   Se l’ogagun nyin l’akoko danwo 

   E je ki ‘ife Re je odi yi nyin ka.


7. Arakunrin, Jesu yio tun pada, 

   N’nu ogo Baba, pel’ awon angeli 

   Gbogbo orile-ede y‘o wariri fun, 

   Okan wa y‘o jewo pe. On ni Oba. Amin

English »

Update Hymn