HYMN 141

S.M. (FE 158)
"Emi o ma yin Oluwa tinutinu mi" - Ps. 111:11. MO f'ope f‘Oluwa 

   Ahon mi nyin Jesu

  Ti a ko ni lat’ewe wa, 

  Lati kaOro Re.


2. B'ese mi ti po to 

   Egbe at'ewu nla 

   Eru s’ese nipa eda 

   Ni Bibeli nko mi.


3. Bibeli l’o nko ni

   B‘a ko tile senkan; 

   Nje nibo l’elese y'o wo, 

   Lati bo n‘nu egbe?


4. lwe Mimo Re yi,

   Jesu, Oluwa mi,

   L'o nf' ona igbala han ni, 

   L'o si nko-ni rere.


5. Ninu re ni mo ko

   Bi Krist'Om'Olorun 

   Ti terigba iya nla wa, 

   Ti O Si ku fun wa.


6. O gunwa li orun

   O nran Emi Re wa 

   Lati fi ife nla Re han 

   At'ilana rere.


7. Emi Mimo, ko mi 

   K'okan mi si le gba 

   Gbogbo ‘wasu oro Re gbo 

   B’awon enia Re.


8. Nigbana, Oluwa 

   L'orin ‘yin mi y‘o ga;

   N'tori t'a ko mi lati ka

   Bibeli mimo Re. Amin

English »

Update Hymn