HYMN 159

t.G.B. 190 (FE 178) 
Ohun Orin: Baba Oludariji1. ALEJO kan ma nkankun 

   Pe wole

   O ti npara ‘be ti pe

   Pe wole

   Pe wole. ki O to lo, 

   Pe wole, Emi Mimo 

   Jesu krist’Omo Baba 

   Pe wole.


2. Silekun okan re fun 

   Pe wole

   B'o ba pe y’o pada lo 

   Pe wole

   Pe wole, Ore re ni 

   Y'o dabobo okan re 

   Y’o pa o mo de opin, 

   Pe wole.


3. O ko ha ngbo ohun Re? 

   Pe wole

   Yan l'ore nisisiyi

   Pe wole

   O nduro lenu ‘lekun 

   Yio fun o li ayo 

   ‘Wo o yin oruko Re 

   Pe wole.


4. P’ Alejo Orun wole 

   Pe wole

   Yio se ase fun o

   Pe wole

   Y’o dari ese ji o, 

   ‘Gbat’ o ba f’aiye sile 

   Y’o mu o de ‘le Orun 

   Pe wole. Amin

English »

Update Hymn