HYMN 161

L.M. (FE 180)1. EMI Orun wa nisisyi

   Mi si wa b‘a ti ngbadura 

   Orisun ‘ye titun ni O,

   Imole ojo wa titun.


2. O mba wa gbe l‘ona ara, 

   lwo ko si jinna si wa

   A o gbo ohun Re Nitosi 

   Emi Re mb'emi wa soro


3. Krist’ l'Alagbawi wa loke 

   Iwo l’Alagbawi n‘nu wa 

   Fi otito da wa lebi 

   Gbogbo awawi ese wa.


4. Okan mi se aigbagbo po! 

   Mo m’ona at’Oluto mi; 

   Dariji mi, Wo Ore mi 

   Fun ‘yapa mi igbukugba.


5. Pelu mi n‘ igba ko s’ore

   Ti mo le f’asiri mi han 

   ‘Gbat'eru Ieke l‘okan mi, 

   Jeki nmo O l’Olutunu. Amin

English »

Update Hymn