HYMN 172

C.M.S 43 H.C. 60 7s (FE 190) 
"Emi o ma yo ninu Oluwa, emi o ma yo ninu 
Olorun igbala mi” - Heb. 3:181. YIN Olorun, yin lailai 

   Fun ife ojojumo

   Orisun ayo gbogbo 

   K’iyin Re gb'enu wa kan.


2. Fun ire t’oko nmu wa 

   Fun onje t’a nmu l’ogba 

   Fun eso igi pelu 

   At’ororo ti a nlo.


3. Fun gbogb’ eran osin wa 

   T’on siri Oka gbogbo 

   Orun ti nse ‘ri sile

   Orun ti nm’oru re wa.


4. Gbogbo nkan t’erun nmu wa, 

   Kakiri gbogbo ile

   At’eso igba ojo

   Lat’ inu ekun re wa.


5. ‘Wo l’elebun gbogbo won, 

   Orisun ibukun wa;

   ‘Torina okan wa y’o 

   F’iyin at’ope fun O.


6. lji lile iba ja

   Ko ba gbogbo oka je

   K’eso igi wo danu 

   Ki akoko re to pe.


7. Ajara ‘ba ma so mo 

   Ki igi gbogbo si gbe 

   K’eran osin gbogbo ku 

   K'eran igbe tan pelu.


8. Sibe, lwo l'okan wa,

   Y‘o f'iyin at'ope fun

   Gbat‘ ibukun gbogbo tan,

   Ao sa fe O fun ‘ra Re. Amin

English »

Update Hymn