HYMN 177

D.S.M1. IJO ti nduro pe

   Lati ri Oluwa

   O si wa bakan na sibe 

   Ko s‘alabaro fun 

   Odun nyi lu odun

   Ojo ngori ojo

   Sibe lairi Oluwa re

   O wa ninu ofo 

   Ma bo, Jesu ma bo!


2. Awon mimo l‘aiye

   Opo won l‘oti ku

   Bi won si ti nlo l’okankan 

   L’a te won gbe ‘ra won

   A te won lati sun

   Ki se ainireti

   A te won lati r'eju ni 

   K'ile ogo to mo 

   Ma bo, Jesu mabo!


3. Awon ola npo si

   Abgara esu nga

   Ogun ngbona, igbagbo nku 

   lfe si di tutu

   Y’o ti pe to Baba

   Oloto Olore

   Wo ki y’o koya omije 

   At’eje Ijo Re

  Ma bo Jesu ma bo!


4. A nfe gbo ohun Re

   A nfe f'oju kan O 

  K‘a le gba ade at' ogo 

  B‘a ti ngha ore Re 

  Jo, wa m‘ese kuro

  A t‘egun at'eri

  K‘o si so aye osi yi

  D‘aye rere Tire

  Ma bo, Jesu ma bo. Amin

English »

Update Hymn