HYMN 186

C.M.S. 55 H.C 62 62 2nd Ed
tabi t. H. C. 173 1.M (FE 204)
“O mbo lati se idajo aiye“ - Ps. 96:131. OLUWA mbo; aiye o mi 

   Oke y'o si di n’ipo won 

   At’irawo oju orun

   Y'o mu imole won kuro.


2. Oluwa mbo, bakanna ko 

   Bi oti wa n'irele ri 

   Odo-agutan ti a pa 

   Eni-iya ti o si ku.


3. Oluwa mbo. li eru nla 

   L‘owo ina pelu Ija 

   L'or'iye apa Kerubu 

   Mbo, Onidajo araiye.


4. Eyi ha li eniti nrin

   Bi ero l’opolopo aiye? 

   'Ti a se 'nunibini si? 

   A! Eniti a pa l’eyi?


5. Ika: b'e wo 'nu apata 

   B'e wo n'nu iho, lasan ni

   Sugbon igbagbo t'osegun

   Y'o korin pe, Oluwa de. Amin

English »

Update Hymn