HYMN 187

C.M.S 48 H.C 64 C.M (FE 205)
"O ti bojuwo, O si ti da awon enia
Re ni ide" - Luke 1:68
1.  GBO 'gbe ayo! Oluwa de,

Jesu t'a seleri

Ki gbogbo okan mura de

K'ohun mura korin.


2.  O de lati t'onde sile

L'oko eru esu

Lekun 'de fo niwaju Re

Sekeseke rin da.


3.  O de larin 'baje aiye 

Lati tan 'mole Re

Lati mu k'awon afoju 

Le f'oju won riran.


4.  O de 'tanu f'okan 'rora

Iwosan f'agbogbe

Pelu 'sura or-ofe Re

Fun awon talaka.


5.  Hosanna, Ob'Alafia 

A o kede bibo Re;

Gbogbo orun y'o ma korin 

oruko t'a feran.  Amin 


English »

Update Hymn